Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alliance and Society with the Enemies of God

229 ẹsẹ · 51 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nínú ìran Elamu: Mattaniah, Sekariah, Jehieli, Abdi, Jerimoti àti Elijah.

  2. Nínú àwọn ìran Sattu: Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, Jerimoti, Sabadi àti Asisa.

  3. Nínú àwọn ìran Bebai: Jehohanani, Hananiah, Sabbai àti Atlai.

  4. Nínú àwọn ìran Bani: Meṣullamu, Malluki, Adaiah, Jaṣubu, Ṣeali àti Jerimoti.

  5. Nínú àwọn Pahati-Moabu: Adma, Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleli, Binnui àti Manase.

  6. Nínú àwọn ìran Harimu: Elieseri, Iṣiah, Malkiah àti Ṣemaiah, Simeoni,

  7. Benjamini, Malluki àti Ṣemariah.

  8. Nínú àwọn ìran Haṣumu: Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifaleti, Jeremai, Manase àti Ṣimei.

  9. Nínú àwọn ìran Bani: Maadai, Amramu, Ueli,

  10. Benaiah, Bediah, Keluhi

  11. Faniah, Meremoti, Eliaṣibu,

  12. Mattaniah, Mattenai àti Jaasu.

  13. Àti Bani, àti Binnui: Ṣimei,

  14. Ṣelemiah, Natani, Adaiah,

  15. Maknadebai, Sasai, Ṣarai,

  16. Asareeli, Ṣelemiah, Ṣemariah,

  17. Ṣallumu, Amariah àti Josẹfu.

  18. Nínú àwọn ìran Nebo: Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Sebina, Jaddai, Joẹli àti Benaiah.

  19. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ obìnrin àjèjì, àwọn mìíràn nínú wọn sì bi ọmọ ní ipasẹ̀ àwọn ìyàwó wọ̀nyí.

  20. Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé, “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi;

  21. bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé, “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?”

  22. Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan.

  23. gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.

  24. “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

  25. “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.