Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflicted Saints

122 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

  2. Èmi ó máa kọrin sí Olúwa, nítorí ó dára sí mi.

  3. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

  4. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

  5. Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí, háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.

  6. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

  7. Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

  8. Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

  9. Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́; èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

  10. Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

  11. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

  12. Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

  13. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ, tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?

  14. Ìwọ kórìíra àṣẹ mi, ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.

  15. Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?

  16. Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

  17. Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

  18. Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú, wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

  19. Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run; ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.

  20. Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ,

  21. ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.

  22. Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ, àti ẹbọ ọ̀rá àgbò; èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.

  23. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

  24. Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

  25. Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.