Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflicted Saints: Should imitate Christ

6 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Should imitate Christ

  1. Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,

  2. kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

  3. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

  4. Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀:

  5. “Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.”

  6. Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.