Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflicted Saints: Paul

4 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Paul

  1. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀.

  2. Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi.

  3. Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìyìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

  4. Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.”