Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflicted Saints: Apostles

8 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Apostles

  1. Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

  2. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,

  3. nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀.

  4. Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.

  5. Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì.

  6. Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́,

  7. bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,

  8. bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.