Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflicted Saints: Should turn and devote themselves to God

6 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Should turn and devote themselves to God

  1. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

  2. Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

  3. nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa ní ilẹ̀ alààyè.

  4. Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbóguntì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.

  5. “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,” ni Olúwa wí, “Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá, àwọn, àti àwọn ọmọ Juda, wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí Olúwa Ọlọ́run wọn.

  6. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.