- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 95
The Revelation
John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ìfihàn 18:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.
- Ìfihàn 18:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní, kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.
- Ìfihàn 18:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́; nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’
- Ìfihàn 18:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn; a ó sì fi iná sun ún pátápátá: nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
- Ìfihàn 18:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀.
- Ìfihàn 18:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Babeli ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’
- Ìfihàn 18:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́.
- Ìfihàn 18:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti perli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu.
- Ìfihàn 18:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.
- Ìfihàn 18:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.
- Ìfihàn 18:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,
- Ìfihàn 18:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali!
- Ìfihàn 18:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré,
- Ìfihàn 18:18nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’
- Ìfihàn 18:19nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’
- Ìfihàn 18:20nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”
- Ìfihàn 18:21nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé: “Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bí i Babeli ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé.
- Ìfihàn 18:22nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin, àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè, ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara; àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé. Àti ìró ọlọ ní a kì yóò sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;
- Ìfihàn 18:23nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé; a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé: nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé; nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ.
- Ìfihàn 18:24nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”
- Ìfihàn 19:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé: “Haleluya! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,
- Ìfihàn 19:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”
- Ìfihàn 19:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé: “Haleluya! Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”
- Ìfihàn 19:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé: “Àmín, Haleluya!”
- Ìfihàn 19:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà!”