Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 7:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”

  2. Johanu 7:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.

  3. Johanu 7:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

  4. Johanu 7:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

  5. Johanu 7:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

  6. Johanu 7:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí?

  7. Johanu 7:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí?

  8. Johanu 7:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

  9. Johanu 7:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,

  10. Johanu 7:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

  11. Johanu 7:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”

  12. Johanu 7:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

  13. Johanu 8:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

  14. Johanu 8:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.

  15. Johanu 8:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín.

  16. Johanu 8:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà.

  17. Johanu 8:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”

  18. Johanu 8:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀.

  19. Johanu 8:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.”

  20. Johanu 8:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

  21. Johanu 8:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà.

  22. Johanu 8:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn olùfisùn rẹ dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

  23. Johanu 8:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

  24. Johanu 8:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

  25. Johanu 8:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”