circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Johanu 8:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.
- Johanu 8:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.
- Johanu 8:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni, nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.
- Johanu 8:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.
- Johanu 8:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”
- Johanu 8:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi, ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”
- Johanu 8:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili, ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.
- Johanu 8:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”
- Johanu 8:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”
- Johanu 8:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí.
- Johanu 8:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
- Johanu 8:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe.
- Johanu 8:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”
- Johanu 8:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn.
- Johanu 8:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ Ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi, ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
- Johanu 8:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”
- Johanu 8:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.
- Johanu 8:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́.
- Johanu 8:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
- Johanu 8:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”
- Johanu 8:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.
- Johanu 8:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé, ọmọ ní ń gbé ilé títí láé.
- Johanu 8:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.
- Johanu 8:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀.
- Johanu 8:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ, ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”