Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 8:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!” Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu.

  2. Johanu 8:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Abrahamu kò ṣe èyí.

  3. Johanu 8:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

  4. Johanu 8:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi, nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi.

  5. Johanu 8:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

  6. Johanu 8:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké.

  7. Johanu 8:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́.

  8. Johanu 8:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́?

  9. Johanu 8:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

  10. Johanu 8:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”

  11. Johanu 8:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi.

  12. Johanu 8:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kò wá ògo ara mi, ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́.

  13. Johanu 8:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”

  14. Johanu 8:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé.’

  15. Johanu 8:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú, ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

  16. Johanu 8:54nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan, Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe.

  17. Johanu 8:55nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.

  18. Johanu 8:56nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi, ó sì rí i, ó sì yọ̀.”

  19. Johanu 8:57nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”

  20. Johanu 8:58nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.”

  21. Johanu 8:59nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú, ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.

  22. Johanu 9:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.

  23. Johanu 9:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

  24. Johanu 9:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀.

  25. Johanu 9:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán, òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.