- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Onidajọ 3:17nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀.
- Onidajọ 3:18nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.
- Onidajọ 3:19nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
- Onidajọ 3:20nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,
- Onidajọ 3:21nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.
- Onidajọ 3:22nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.
- Onidajọ 3:23nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
- Onidajọ 3:24nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”
- Onidajọ 3:25nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
- Onidajọ 3:26nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira.
- Onidajọ 3:27nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn.
- Onidajọ 3:28nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
- Onidajọ 3:29nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
- Onidajọ 3:30nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.
- Onidajọ 3:31nǹkan bí 1325 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ẹgbẹ̀ta (600) Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.
- Onidajọ 4:1nǹkan bí 1305 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa.
- Onidajọ 4:2nǹkan bí 1305 ṣáájú Kristi
Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu.
- Onidajọ 4:3nǹkan bí 1305 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.
- Onidajọ 4:4nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà.
- Onidajọ 4:5nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀.
- Onidajọ 4:6nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori.
- Onidajọ 4:7nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ”
- Onidajọ 4:8nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”
- Onidajọ 4:9nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi.
- Onidajọ 4:10nǹkan bí 1285 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.