- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
Jehoaṣi ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jehoiada àlùfáà fi àṣẹ fún un.
Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn ní ìdí, àwọn ènìyàn sì tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ àti sísun tùràrí níbẹ̀.
- 2 Ọba 12:4nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
- 2 Ọba 12:5nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún tuntun ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
- 2 Ọba 12:6nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
- 2 Ọba 12:7nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ọba Jehoaṣi pe Jehoiada àlùfáà àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún títún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
- 2 Ọba 12:8nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Àwọn àlùfáà fi ara mọ́ pé wọn kò nígbà owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sì ni, wọn kò sì ní tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe mọ́ fúnra wọn.
- 2 Ọba 12:9nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Jehoiada àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
- 2 Ọba 12:10nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé ọba àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.
- 2 Ọba 12:11nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.
- 2 Ọba 12:12nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún tuntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹmpili ṣe.
- 2 Ọba 12:13nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, ohun èlò ta fi ń fa ẹnu fìtílà, àwokòtò, ìpè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
- 2 Ọba 12:14nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
- 2 Ọba 12:15nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà ṣírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé.
- 2 Ọba 12:16nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa, ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.
- 2 Ọba 12:17nǹkan bí 840 ṣáájú Kristi
Ní déédé àkókò yìí, Hasaeli ọba Siria gòkè lọ láti dojúkọ Gati àti láti fi agbára mú un. Nígbà náà, ó yípadà láti dojúkọ Jerusalẹmu.
- 2 Ọba 12:18nǹkan bí 840 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀ Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu.
- 2 Ọba 12:19nǹkan bí 840 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Joaṣi, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
- 2 Ọba 12:20nǹkan bí 840 ṣáájú Kristi
Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Beti-Milo ní ọ̀nà sí Silla.
- 2 Ọba 12:21nǹkan bí 840 ṣáájú Kristi
Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Josabadi ọmọ Ṣimeati àti Jehosabadi ọmọ Ṣomeri. Ó kú, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún.
- 2 Ọba 13:2nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn.
- 2 Ọba 13:3nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.
- 2 Ọba 13:4nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi.
- 2 Ọba 13:5nǹkan bí 856 ṣáájú Kristi
Olúwa pèsè olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.