Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Ọba 5:5nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìwọ̀n wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá.

  2. 2 Ọba 5:6nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé, “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

  3. 2 Ọba 5:7nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

  4. 2 Ọba 5:8nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé, “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.”

  5. 2 Ọba 5:9nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa.

  6. 2 Ọba 5:10nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

  7. 2 Ọba 5:11nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn.

  8. 2 Ọba 5:12nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.

  9. 2 Ọba 5:13nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!”

  10. 2 Ọba 5:14nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

  11. 2 Ọba 5:15nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Naamani àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsin yìí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Israẹli nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

  12. 2 Ọba 5:16nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò nígbà ohun kan,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naamani rọ̀ ọ́ láti gbà á, ó kọ̀.

  13. 2 Ọba 5:17nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Naamani wí pé, “Tí o kò bá nígbà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fi fún èmi ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ẹrù erùpẹ̀ tí ìbáaka méjì le rù, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rú ẹbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn mọ́ bí kò ṣe sí Olúwa.

  14. 2 Ọba 5:18nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí. Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rimoni láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rimoni, kí Olúwa dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

  15. 2 Ọba 5:19nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa wí pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Lẹ́yìn ìgbà tí Naamani tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà,

  16. 2 Ọba 5:20nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Gehasi, ìránṣẹ́ Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ́nú lórí Naamani, ará Aramu, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ní ọwọ́ rẹ̀.”

  17. 2 Ọba 5:21nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáradára?” ó béèrè.

  18. 2 Ọba 5:22nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    “Gbogbo nǹkan wà dáradára,” Gehasi dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Efraimu. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

  19. 2 Ọba 5:23nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Naamani wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Gehasi láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Gehasi.

  20. 2 Ọba 5:24nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Gehasi sì dé ibi ilé ìṣọ́, ó gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn, ó sì tó wọ́n sínú ilé, ó sì jọ̀wọ́ àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ lọ, wọ́n sì jáde lọ.

  21. 2 Ọba 5:25nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa. “Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè. “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn.

  22. 2 Ọba 5:26nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin?

  23. 2 Ọba 5:27nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  24. 2 Ọba 6:1nǹkan bí 893 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Eliṣa pé, “Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa.

  25. 2 Ọba 6:2nǹkan bí 893 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jordani, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.” Ó sì wí pé, “Lọ.”