Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Ọba 4:24nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.”

  2. 2 Ọba 4:25nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Karmeli. Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi, “Wò ó! Ará Ṣunemu nì!

  3. 2 Ọba 4:26nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.”

  4. 2 Ọba 4:27nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Gehasi wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”

  5. 2 Ọba 4:28nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pé kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?”

  6. 2 Ọba 4:29nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa wí fún Gehasi pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.”

  7. 2 Ọba 4:30nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láààyè, èmi kò ní í fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

  8. 2 Ọba 4:31nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Gehasi sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn tàbí ìdáhùn. Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi padà lọ láti lọ bá Eliṣa láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

  9. 2 Ọba 4:32nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn.

  10. 2 Ọba 4:33nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

  11. 2 Ọba 4:34nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná.

  12. 2 Ọba 4:35nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀.

  13. 2 Ọba 4:36nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.”

  14. 2 Ọba 4:37nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

  15. 2 Ọba 4:38nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”

  16. 2 Ọba 4:39nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà igbó. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ, ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ.

  17. 2 Ọba 4:40nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sọkún jáde, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí!” Wọn kò sì le jẹ ẹ́.

  18. 2 Ọba 4:41nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Eliṣa sì wí pé, “Mú ìyẹ̀fun díẹ̀ wá,” Ó sì fi sínú ìkòkò ó sì wí pé, “Kí ó sì fi fún àwọn ènìyàn láti jẹ.” Kò sì sí ohun tí ó léwu nínú ìkòkò náà.

  19. 2 Ọba 4:42nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin kan wá láti Baali-Ṣaliṣa, ó sì mú àkàrà àkọ́so èso, ogún ìṣù àkàrà barle, tí wọ́n dín láti ara àkọ́so èso àgbàdo, àti pẹ̀lú síírí ọkà tuntun nínú àpò rẹ̀ wá fún ènìyàn Ọlọ́run náà. Òun sì wí pé, “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ.”

  20. 2 Ọba 4:43nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    “Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́rùn-ún ènìyàn?” ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè. Ṣùgbọ́n Eliṣa dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún ṣẹ́kù.’ ”

  21. 2 Ọba 4:44nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

  22. 2 Ọba 5:1nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

  23. 2 Ọba 5:2nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani.

  24. 2 Ọba 5:3nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

  25. 2 Ọba 5:4nǹkan bí 894 ṣáájú Kristi

    Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ.