Fò sí àkóónú

circa 970–930 BC

Solomon & The Temple

Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.

635 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 7:12nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.

  2. 2 Kronika 7:13nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi,

  3. 2 Kronika 7:14nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.

  4. 2 Kronika 7:15nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí.

  5. 2 Kronika 7:16nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.

  6. 2 Kronika 7:17nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run,

  7. 2 Kronika 7:18nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli.

  8. 2 Kronika 7:19nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n,

  9. 2 Kronika 7:20nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    nígbà náà ni èmi yóò fa Israẹli tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrín gbogbo ènìyàn,

  10. 2 Kronika 7:21nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí Olúwa fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’

  11. 2 Kronika 7:22nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”

  12. 2 Kronika 8:1nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnra rẹ̀.

  13. 2 Kronika 8:2nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀.

  14. 2 Kronika 8:3nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀.

  15. 2 Kronika 8:4nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati.

  16. 2 Kronika 8:5nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.

  17. 2 Kronika 8:6nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.

  18. 2 Kronika 8:7nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli,

  19. 2 Kronika 8:8nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.

  20. 2 Kronika 8:9nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Solomoni kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

  21. 2 Kronika 8:10nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba (250) àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn.

  22. 2 Kronika 8:11nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

  23. 2 Kronika 8:12nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa,

  24. 2 Kronika 8:13nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́.

  25. 2 Kronika 8:14nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi

    Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.