Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 18:12nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Saulu sì ń bẹ̀rù Dafidi nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi, ṣùgbọ́n ó ti fi Saulu sílẹ̀.

  2. 1 Samuẹli 18:13nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ó sì lé Dafidi jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan (1,000), Dafidi ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

  3. 1 Samuẹli 18:14nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì ṣe ọlọ́gbọ́n ní gbogbo ìṣe rẹ̀, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

  4. 1 Samuẹli 18:15nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.

  5. 1 Samuẹli 18:16nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli àti Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó darí wọn lọ ní ìgbòkègbodò ogun wọn.

  6. 1 Samuẹli 18:17nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.”

  7. 1 Samuẹli 18:18nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?”

  8. 1 Samuẹli 18:19nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya.

  9. 1 Samuẹli 18:20nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí ọmọbìnrin Saulu Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, nígbà tí wọ́n sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.

  10. 1 Samuẹli 18:21nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ ìkẹ́kùn fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Filistini lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Dafidi pé, “Nísinsin yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna án mi.”

  11. 1 Samuẹli 18:22nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Saulu pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dafidi ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsin yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

  12. 1 Samuẹli 18:23nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dafidi. Ṣùgbọ́n Dafidi wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”

  13. 1 Samuẹli 18:24nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Saulu sọ fún un ohun tí Dafidi sọ,

  14. 1 Samuẹli 18:25nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Saulu dáhùn pé, “Sọ fún Dafidi pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn-ún Filistini lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ ” Èrò Saulu ni wí pé kí Dafidi ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Filistini.

  15. 1 Samuẹli 18:26nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá,

  16. 1 Samuẹli 18:27nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya.

  17. 1 Samuẹli 18:28nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi,

  18. 1 Samuẹli 18:29nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Saulu sì tún wá bẹ̀rù Dafidi síwájú àti síwájú, Saulu sì wá di ọ̀tá Dafidi fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tókù.

  19. 1 Samuẹli 18:30nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ-aládé Filistini tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dafidi ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Saulu lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.

  20. 1 Samuẹli 19:1nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀

  21. 1 Samuẹli 19:2nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀.

  22. 1 Samuẹli 19:3nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”

  23. 1 Samuẹli 19:4nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.

  24. 1 Samuẹli 19:5nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?”

  25. 1 Samuẹli 19:6nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”