Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 15:28nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sì wí fún un pé, “Olúwa ti fa ìjọba Israẹli ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ.

  2. 1 Samuẹli 15:29nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Ẹni tí ó ń ṣe ògo Israẹli, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”

  3. 1 Samuẹli 15:30nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbàgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Israẹli, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.”

  4. 1 Samuẹli 15:31nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli sì yípadà pẹ̀lú Saulu, Saulu sì sin Olúwa.

  5. 1 Samuẹli 15:32nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Samuẹli wí pé, “Mú Agagi ọba àwọn ará Amaleki wá fún mi.” Agagi sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”

  6. 1 Samuẹli 15:33nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàrín obìnrin.” Samuẹli sì pa Agagi níwájú Olúwa ni Gilgali.

  7. 1 Samuẹli 15:34nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu.

  8. 1 Samuẹli 15:35nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Samuẹli kò sì padà wá mọ́ láti wo Saulu títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Samuẹli káàánú fún Saulu. Ó sì dun Olúwa pé ó fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli.

  9. 1 Samuẹli 16:1nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Saulu, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jese ará Bẹtilẹhẹmu. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”

  10. 1 Samuẹli 16:2nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.” Olúwa wí pé, “Mú abo ẹgbọrọ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa.’

  11. 1 Samuẹli 16:3nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Pe Jese wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fihàn ọ́.”

  12. 1 Samuẹli 16:4nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Samuẹli ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”

  13. 1 Samuẹli 16:5nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.

  14. 1 Samuẹli 16:6nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

  15. 1 Samuẹli 16:7nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

  16. 1 Samuẹli 16:8nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Jese pe Abinadabu, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Samuẹli. Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.”

  17. 1 Samuẹli 16:9nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Jese sì jẹ́ kí Ṣamma rìn kọjá ní iwájú Samuẹli, ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.”

  18. 1 Samuẹli 16:10nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Jese jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Samuẹli ṣùgbọ́n Samuẹli sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.”

  19. 1 Samuẹli 16:11nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?” Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.” Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

  20. 1 Samuẹli 16:12nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.”

  21. 1 Samuẹli 16:13nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí Mímọ́ Olúwa wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.

  22. 1 Samuẹli 16:14nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, ẹ̀mí Olúwa ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.

  23. 1 Samuẹli 16:15nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.

  24. 1 Samuẹli 16:16nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”

  25. 1 Samuẹli 16:17nǹkan bí 1063 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”