Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 14:30nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀tá wọn lónìí, pípa àwọn Filistini ìbá ti pọ̀ tó?”

  2. 1 Samuẹli 14:31nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà.

  3. 1 Samuẹli 14:32nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀.

  4. 1 Samuẹli 14:33nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.” Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.”

  5. 1 Samuẹli 14:34nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

  6. 1 Samuẹli 14:35nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

  7. 1 Samuẹli 14:36nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.” Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”

  8. 1 Samuẹli 14:37nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

  9. 1 Samuẹli 14:38nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Ẹ wá síyìn-ín ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí.

  10. 1 Samuẹli 14:39nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

  11. 1 Samuẹli 14:40nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu wí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jonatani ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”

  12. 1 Samuẹli 14:41nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

  13. 1 Samuẹli 14:42nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Ẹ dìbò láàrín èmi àti Jonatani ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jonatani.

  14. 1 Samuẹli 14:43nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí fún Jonatani pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.” Jonatani sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsin yìí ṣé mo ní láti kú?”

  15. 1 Samuẹli 14:44nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, nítorí pé ìwọ Jonatani yóò sá à kú dandan.”

  16. 1 Samuẹli 14:45nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Saulu pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jonatani kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Israẹli? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jonatani sílẹ̀, kò sì kú.

  17. 1 Samuẹli 14:46nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu sì dẹ́kun lílépa àwọn Filistini, àwọn Filistini sì padà sí ìlú wọn.

  18. 1 Samuẹli 14:47nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí Saulu ti jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni; Edomu, àti àwọn ọba Soba, àti àwọn Filistini. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n.

  19. 1 Samuẹli 14:48nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Ó sì jà tagbára tagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Amaleki, ó sì ń gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n.

  20. 1 Samuẹli 14:49nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali.

  21. 1 Samuẹli 14:50nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Ahinoamu ọmọbìnrin Ahimasi. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arákùnrin baba Saulu.

  22. 1 Samuẹli 14:51nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Kiṣi baba Saulu àti Neri baba Abneri wọ́n sì jẹ́ ọmọ Abieli.

  23. 1 Samuẹli 14:52nǹkan bí 1087 ṣáájú Kristi

    Ní gbogbo ọjọ́ Saulu, ogun náà sì gbóná sí àwọn Filistini, níbikíbi tí Saulu bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.

  24. 1 Samuẹli 15:1nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Samuẹli wí fún Saulu pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli; fetísílẹ̀ láti gbọ́ iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́.

  25. 1 Samuẹli 15:2nǹkan bí 1079 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò jẹ àwọn Amaleki ní yà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ejibiti.