Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀.

  2. Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ mọ́.

  3. “Rántí ìlànà tí o fún Mose ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, ‘Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè.

  4. gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú ibodè omi. Wọ́n sọ fún Esra akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mose jáde, èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún Israẹli.

  5. Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípasẹ̀ Mose, kí àwọn ọmọ Israẹli gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje

  6. Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ.

  7. gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.

  8. Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.

  9. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

  10. Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run. Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.

  11. Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

  12. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;

  13. Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, àti Aaroni tí ó ti yàn.

  14. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

  15. Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.

  16. Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.

  17. Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,

  18. ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

  19. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!

  20. Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.

  21. Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ.

  22. Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.

  23. “Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”

  24. Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”

  25. Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀.