Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”

  2. Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?”

  3. Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀.

  4. wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.

  5. Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mose pàṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a mú láradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”

  6. Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’

  7. Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.

  8. Peteru sì wí fún Jesu pé, “Rabbi, ó dára fún wa láti máa gbé níhìn-ín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”

  9. Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”

  10. Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”

  11. “Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé, nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.

  12. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  13. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa

  14. Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”

  15. Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀,

  16. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)

  17. “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’

  18. “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”

  19. wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé, Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.

  20. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’

  21. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

  22. Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé, a ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”

  23. Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.

  24. Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

  25. Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú.