Fò sí àkóónú

Joseph

199 ẹsẹ · 17 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Joseph

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao.

  2. Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti.

  3. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni.

  4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Josẹfu padà sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

  5. Nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Josẹfu ṣì fi wá sínú ń kọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀san gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?”

  6. Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Josẹfu wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé,

  7. ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Josẹfu, mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjì àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Josẹfu sọkún.

  8. Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí?

  9. Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà ọdún.

  10. Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn.

  11. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.”

  12. Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.”

  13. Báyìí ni Josẹfu kú nígbà tí ó pé àádọ́fà ọdún. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Ejibiti.

  14. Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti.

  15. Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú,

  16. Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti.

  17. Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.”

  18. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Josẹfu: láti ọ̀dọ̀ Efraimu, Eliṣama ọmọ Ammihudu. Láti ọ̀dọ̀ Manase, Gamalieli ọmọ Pedasuri.

  19. Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu. Láti ìran Efraimu, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

  20. láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;

  21. Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.

  22. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

  23. Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  24. Nígbà náà Mose fún àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu ní ilẹ̀ ọba Sihoni ọba àwọn ọmọ Amori àti ilẹ̀ ọba Ogu ọba Baṣani ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbègbè tí ó yí i ka.

  25. Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,