Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Brother

25 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,

  2. ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.

  3. Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Josẹfu yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sọkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sọkún níbẹ̀.

  4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun.

  5. Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Ejibiti tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Ejibiti kò le bá ará Heberu jẹun nítorí ìríra pátápátá ló jẹ́ fún àwọn Ejibiti.

  6. A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátápátá dé orí èyí tí ó kéré pátápátá, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu.

  7. A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Josẹfu. Oúnjẹ Benjamini sì tó ìlọ́po márùn-ún ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.

  8. Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀.

  9. Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.

  10. Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀.

  11. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti!

  12. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín.

  13. Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí?

  14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là.

  15. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn.

  16. Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà ọdún.

  17. Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn.

  18. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.”

  19. Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.”

  20. Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un.

  21. Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má ba á parẹ́ ní Israẹli.

  22. Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”

  23. Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,”

  24. opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”

  25. A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”