Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli, àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu, kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lù wọ́n bolẹ̀, ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  2. Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

  3. Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.

  4. Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  5. “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

  6. Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

  7. Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.

  8. Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.

  9. Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

  10. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu: “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́; ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

  11. Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.

  12. Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

  13. Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu? Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli, “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

  14. “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,

  15. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

  16. “Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí. “Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí,

  17. Ta ni ó fi Jakọbu lélẹ̀ fún ìkógun, àti Israẹli sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í ha ṣe Olúwa ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

  18. Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí, ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu, ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.

  19. “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli.

  20. Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.

  21. “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.

  22. Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.

  23. Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’; òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu; bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’ yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.

  24. “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu, nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.

  25. Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.