- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Israel
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel
Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin, láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn, Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé, ‘Ẹ wá mi lórí asán.’ Èmi Olúwa sọ òtítọ́, Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu Israẹli ẹni tí mo pè. Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
Nísinsin yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi,
Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”
Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
“Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn, àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.
“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.
Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.
Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu, àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì; àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.
Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.
A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.
“Kéde èyí fún ilé Jakọbu, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.
Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́n, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’
Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.
Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’
Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.