Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọdún keje ọba Artasasta díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili náà gòkè wá sí Jerusalẹmu.

  2. Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.

  3. Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi.

  4. Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,

  5. Wọ́n ri ní àkọsílẹ̀ nínú ìwé òfin, èyí tí Olúwa ti pa ní àṣẹ nípasẹ̀ Mose, kí àwọn ọmọ Israẹli gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ àgọ́ oṣù keje

  6. Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n padà láti ìgbèkùn kọ́ àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú wọn. Láti ọjọ́ Jeṣua ọmọ Nuni títí di ọjọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli kò tí ì ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀ bí irú èyí. Ayọ̀ ọ wọn sì pọ̀.

  7. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọpọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn.

  8. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

  9. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí. (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún.)

  10. Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá! Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

  11. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

  12. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!

  13. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

  14. Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.

  15. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

  16. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa; Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

  17. Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa, ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.

  18. Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni! Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!

  19. pa wọ́n run nínú ìbínú, run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́. Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

  20. Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.

  21. Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.

  22. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.

  23. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,

  24. Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,

  25. Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu àti Israẹli ogún un rẹ̀.