Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe: “Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn, iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni: ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ ojú kì yóò tì í.”

  2. Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.

  3. Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.

  4. Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí.

  5. Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn.

  6. Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

  7. Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ́ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba.

  8. Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run.

  9. Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  10. ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

  11. Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn.

  12. Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.

  13. Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.

  14. Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.

  15. àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ.

  16. Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi.

  17. Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.

  18. Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.

  19. Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìyìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

  20. Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

  21. Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  22. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.

  23. Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín.

  24. Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í, ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí.

  25. Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá, bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìyìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?