Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.

  2. Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀.

  3. Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn,

  4. Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.

  5. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.

  6. A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.

  7. bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìyìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa.

  8. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.

  9. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

  10. ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.

  11. Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

  12. Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù,

  13. àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn

  14. Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìyìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín.

  15. Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.

  16. À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í.

  17. Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

  18. Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsin yìí, a béèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jesu Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí.

  19. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè,

  20. kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run;

  21. Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́.

  22. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.

  23. Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín.

  24. A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá.

  25. Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.