God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀, èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.
Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”
Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.
“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé. Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.
“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”
Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò, tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.
Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà, láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ. “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án.
Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?
Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.
Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.
Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.
Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.
Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.
Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli. Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.
“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá, ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”
Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀, ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀? Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa; òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.
Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.