God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun, tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ. Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi, tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí. Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi, tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀; àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
“Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’; òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu; bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’ yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”
“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu, nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni Olúwa tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’ àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’ àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn, Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.