God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’
Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,
ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀; lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin; bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.
Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’
Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn. Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí? “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.
A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní. Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’
Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò.
Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí. Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu Israẹli ẹni tí mo pè. Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.
“Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́. Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí. Olúwa ti fẹ́ ẹ, yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni, apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.
“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú aginjù; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde.
“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn ìkà.”