God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi. Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan, ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà, àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá sí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn erékùṣù yóò wò mí wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run, wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀; àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín, ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé, òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ, ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”
Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára ìwọ apá Olúwa; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
“Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́, “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n; láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́, láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí. “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti gbé; láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.