Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni Olúwa wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.

  2. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

  3. Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

  4. Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.

  5. Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.

  6. Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.

  7. Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.

  8. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò tàbí kí ẹ sáré lọ; nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ, Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

  9. Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n; òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga a ó sì gbé e lékè gidigidi.

  10. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.

  11. Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?

  12. Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀. Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.

  13. Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

  14. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.

  15. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

  16. Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

  17. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

  18. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

  19. “Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni Olúwa wí.

  20. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.

  21. Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí.

  22. “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá.

  23. Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

  24. “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.

  25. Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí, síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.