God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri tí a kò sì tù nínú, Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ, àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
“Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.
Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi; gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè. Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ, ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ Ẹni Mímọ́ Israẹli nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”
Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i; ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀. Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un, àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.
“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni Olúwa wí.
“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ.
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.
Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ. Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa, fún àmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun.”
Èyí ni ohun ti Olúwa sọ: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, “Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”
Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò.
Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì! Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín; àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?