Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Water

197 ẹsẹ · 84 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru.

  2. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.

  3. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà sì padà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì jẹ oúnjẹ ó sì mu omi ní ilé rẹ̀.

  4. Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”

  5. Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.

  6. Ahabu sì ti wí fún Obadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.”

  7. Nígbà náà ni iná Olúwa bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ sísun náà àti igi, àti àwọn òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrá náà.

  8. Wọ́n sì wẹ kẹ̀kẹ́ náà ní adágún Samaria, àwọn ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn àgbèrè sì wẹ ara wọn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti sọ.

  9. Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jordani.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

  10. Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jíjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Elijah àti Eliṣa ti dúró ní Jordani.

  11. Elijah sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

  12. Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Elijah wà?” Ó béèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, Eliṣa sì rékọjá.

  13. Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé, “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.”

  14. Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

  15. Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ”

  16. Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ.

  17. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli jáde lọ pẹ̀lú ọba Juda àti ọba Edomu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ-ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  18. “Kí ni?” ọba Israẹli kígbe sókè. “Ṣé Olúwa pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́?”

  19. Nítorí èyí ni Olúwa wí, o kò ní í rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.

  20. Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa, yóò sì fi Moabu lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.

  21. Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódi àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú. Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run.”

  22. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ, níbẹ̀ ni omí sàn láti ọ̀kánkán Edomu! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi.

  23. Nísinsin yìí gbogbo ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.

  24. Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, oòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Moabu ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀.

  25. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.