Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Water: The sea
Àwọn ẹsẹ nípa The sea
Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.
Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.