Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Walls

89 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le

  2. Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.

  3. Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́.

  4. Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.

  5. Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì padà sí agbègbè ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná sun ẹnu ibodè rẹ̀.”

  6. Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

  7. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

  8. Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;

  9. bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.

  10. Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

  11. Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”.

  12. Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn.

  13. Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.

  14. Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri; ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.

  15. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

  16. Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

  17. ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà.

  18. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.

  19. Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.

  20. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

  21. Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.

  22. Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

  23. fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò,

  24. Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

  25. Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.