Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Walls: Destruction of, a punishment and cause of grief

8 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Destruction of, a punishment and cause of grief

  1. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.

  2. Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì padà sí agbègbè ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná sun ẹnu ibodè rẹ̀.”

  3. Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

  4. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

  5. Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;

  6. bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.

  7. Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

  8. Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”.