Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Walls

89 ẹsẹ · 48 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Tekeli: A ti gbé ọ lórí òsùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.

  2. “Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.”

  3. Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́.

  5. Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.

  6. Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run.

  7. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.

  8. Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

  9. Olúwa wí pé: Èmi ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’

  10. Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.

  11. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

  12. Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”

  13. Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

  14. Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín.