Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Titles and Names of the Church

50 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.

  2. “Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

  3. Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

  4. Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ; di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

  5. Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀, iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.

  6. Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú; má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.

  7. Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

  8. Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

  9. Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba.

  10. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

  11. Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

  12. Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.

  13. Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ọ̀rẹ́ Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.

  14. Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”

  15. Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

  16. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

  17. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”

  18. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọláńlá mi hàn.

  19. A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́, ẹni ìràpadà Olúwa; a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri, ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.

  20. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

  21. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.

  22. Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.

  23. Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

  24. Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”

  25. Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan.