Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Wisdom of God
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.
Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa, mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.
Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́? Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?
Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé, Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
“Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ? Ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni. Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.
Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.
Ní ọdún kejì ìjọba Nebukadnessari, ó lá àlá, èyí tí ó mú kí ọkàn an rẹ̀ dàrú, kò sì le è sùn.
Daniẹli wí pé: “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé; tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.
Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.
Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sì í Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ.
Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.
Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé.
“Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.