Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reprobacy

150 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run.

  2. Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  3. Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  4. Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.

  5. Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà.

  6. Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.

  7. Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.

  8. Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.

  9. Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀; èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa?’

  10. Èmi yóò sì pa ojú mi mọ́ dájúdájú ní ọjọ́ náà nítorí i gbogbo ìwà búburú wọn ní yíyípadà sí ọlọ́run mìíràn.

  11. “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Israẹli kò ní tẹríba fún mi.

  12. Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

  13. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

  14. níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

  15. Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.

  16. Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

  17. “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

  18. Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé, “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

  19. Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dìwọ́n ní ojú. Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran, kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀, kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn, kí wọn kí ó má ba yípadà kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

  20. Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti sọkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

  21. Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

  22. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  23. Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé, ṣe èyí, ṣe ìyẹn, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.

  24. Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran; ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.

  25. Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín: ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì; ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.