Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Psalms

896 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà: nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.

  2. Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

  3. Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.

  4. Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.

  5. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.

  6. Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

  7. Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.

  8. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.

  9. Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.

  10. Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé, mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

  11. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.

  12. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

  13. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.

  14. Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró láé.

  15. Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn: olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.

  16. Ènìyàn rere fi ojúrere hàn, a sì wínni; ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

  17. Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé: olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.

  18. Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú: ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

  19. Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  20. Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú, nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.

  21. Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́, yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù: èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

  22. Ẹ máa yin Olúwa. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ yin orúkọ Olúwa.

  23. Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

  24. Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

  25. Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.