Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prayer

720 ẹsẹ · 120 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.

  2. Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  3. Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.

  4. Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.

  5. Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.

  6. Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn

  7. Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀.

  8. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba kí aya rẹ̀ sì di opó.

  9. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn.

  10. Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.

  11. Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un tàbí kí wọn káàánú lórí àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba.

  12. Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀.

  13. Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.

  14. Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

  15. Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.

  16. Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.

  17. Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi.

  18. Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo.

  19. Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.

  20. Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè, ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ. Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.

  21. Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí, àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

  22. Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́, mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.

  23. Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.

  24. Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi; nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.

  25. Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.