Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prayer: Answered

58 ẹsẹ · 120 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Answered

Sẹ́ nípa ìwé
  1. kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.

  2. Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

  3. Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Dafidi. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

  4. Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.

  5. Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.

  6. Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.

  7. Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.

  8. Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

  9. Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

  10. Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

  11. Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

  12. Alábùkún fún ni Olúwa! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

  13. Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ sì ti wò mí sàn.

  14. Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

  15. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

  16. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

  17. Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n.

  18. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

  19. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

  20. ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́ ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.

  21. Ìyìn ni fún Ọlọ́run ẹni tí kò kọ àdúrà mi tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!

  22. Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu. Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

  23. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.

  24. Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

  25. Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.