Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prayer: Imprecatory prayers

114 ẹsẹ · 120 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Imprecatory prayers

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”

  2. Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”

  3. Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn.

  4. “Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí,” Balaamu sọ fún un pé, “èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí Olúwa bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Moabu dúró sọ́dọ̀ rẹ̀.

  5. Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?”

  6. Balaamu sọ fún Ọlọ́run pé, “Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé,

  7. ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”

  8. Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé, “Balaki mú mi láti Aramu wá, ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’

  9. Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú? Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí Olúwa kò bá wí?

  10. Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

  11. Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.

  12. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali.

  13. Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali.

  14. Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

  15. Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.

  16. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

  17. Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

  18. Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  19. Lẹ́yìn èyí, Joṣua sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin, ìbùkún àti ègún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin.

  20. Nígbà náà ni Samsoni ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.”

  21. Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé, ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘Kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

  22. Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri, ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un.

  23. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”

  24. Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbèkùn.

  25. Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé.