Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ploughing

21 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.”

  2. Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.

  3. Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó.

  5. oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn,

  6. Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.

  7. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn.

  8. Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

  9. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  10. Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

  11. Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

  12. Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

  13. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu: “Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí, kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.

  14. Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà; lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹrù wúwo lé. Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin Juda yóò tú ilẹ̀, Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.

  15. Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

  16. Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín,

  17. Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.

  18. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  19. Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”

  20. “Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’?

  21. Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè.