Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Perseverance

159 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

  2. Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa.

  3. Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

  4. Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú.

  5. Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.

  6. Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run Baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa.

  7. Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

  8. Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.

  9. Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

  10. Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu.

  11. Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.

  12. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.

  13. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba. Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.

  14. Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn.

  15. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.

  16. Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  17. Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

  18. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan.

  19. Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn.

  20. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

  21. Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin.

  22. Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin.

  23. Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run,

  24. Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́,

  25. tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀,