Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Law

175 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

  2. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

  3. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’

  4. Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

  5. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’

  6. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni.

  7. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba ńlá ni.

  8. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.

  9. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

  10. “Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’

  11. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú.

  12. Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.

  13. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.

  14. Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.

  15. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’

  16. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.

  17. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo.

  18. “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu, Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.

  19. Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí èyí tí ó kéré jù nínú òfin kí ó yẹ.

  20. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”

  21. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

  22. “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”

  23. Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

  24. Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

  25. Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba.