- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kings
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!”
Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.
“Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.
“Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.”
Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró.
Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.”
Eliṣa kú a sì sin ín. Ẹgbẹ́ àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún.
Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba.
Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.
Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.
Ní ọdún kejì tí Jehoaṣi ọmọ Joahasi ọba Israẹli, Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani; ó wá láti Jerusalẹmu.
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dafidi baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ baba a rẹ̀ Joaṣi.
Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò, àwọn ènìyàn sì tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọingbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.
Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ará Edomu ní àfonífojì iyọ̀, ó sì fi agbára mú Sela nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jokteeli, orúkọ tí ó ní títí di òní.
Nígbà náà, Amasiah rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu ọba Israẹli pẹ̀lú ìpèníjà: “Wá, jẹ́ kí á wo ara wa ní ojú.”
Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì sí Amasiah ọba Juda: “Òṣùṣú kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí kedari ní Lebanoni, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú igbó ní Lebanoni wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.
Ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”
Bí ó ti wù kí ó rí Amasiah kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi ọba Israẹli sì dojúkọ ọ́. Òun àti Amasiah ọba Juda kọjú sí ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda.
A kó ipa ọ̀nà Juda nípasẹ̀ Israẹli, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.
Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́.