Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Journey of Israel Through The Desert
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Mose sọ fún Olúwa wí pé,
“Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí,
láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”
Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.
Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn.
Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.
Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”
Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ.
Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Olúwa sọ fún Mose pé,
“Gbẹ̀san lára àwọn Midiani fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”
Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Midiani láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn.
Rán ẹgbẹ̀rún (1,000) ọmọ-ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Israẹli.”
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn Israẹli, ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.
Mose rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1,000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Finehasi ọmọ Eleasari, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n dojú ìjà kọ Midiani gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, kí wọn sì pa gbogbo wọn.
Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori.
Àwọn ọmọ Israẹli sì mú gbogbo obìnrin Midiani ní ìgbèkùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn.
Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn.
Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran.
Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Israẹli ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani létí Jeriko.
Mose, Eleasari àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbèríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.
Inú bí Mose sí àwọn olórí ọmọ-ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún tí wọ́n ti ogun dé.
Mose sì béèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?
Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Israẹli padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Peori, níbi tí àjàkálẹ̀-ààrùn ti kọlu ìjọ Olúwa.